John 18:29-38

29 aNítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”

30Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”

31Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”

Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”
32 bKí ọ̀rọ̀ Jesu ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

33Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”

34Jesu dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”

35Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́: kín ní ìwọ ṣe?”

36 cJesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”

37 dNítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?”

Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”

38 ePilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.
Copyright information for YorBMYO